Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 41:2-12 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ṣé o lè fi okùn sí imú rẹ̀,tabi kí o fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní àgbọ̀n?

3. Ṣé yóo bẹ̀ ọ́,tabi kí ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀?

4. Ṣé yóo bá ọ dá majẹmu,pé kí o fi òun ṣe iranṣẹ títí lae?

5. Ṣé o lè máa fi ṣeré bí ọmọ ẹyẹ,tabi kí o dè é lókùn fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ?

6. Ṣé àwọn oníṣòwò lè yọwó rẹ̀?Àbí wọ́n lè pín Lefiatani láàrin ara wọn?

7. Ṣé o lè fi ọ̀kọ̀ gún ẹran ara rẹ̀,tabi kí o fi ẹ̀sín àwọn apẹja gún orí rẹ̀?

8. Lọ fọwọ́ kàn án;kí o wo irú ìjà tí yóo bá ọ jà;o kò sì ní dán irú rẹ̀ wò mọ́ lae!

9. “Ìrètí ẹni tí ó bá fẹ́ bá a jà yóo di òfo,nítorí ojora yóo mú un nígbà tí ó bá rí i.

10. Ta ló láyà láti lọ jí i níbi tí ó bá sùn sí?Ta ló tó kò ó lójú?

11. Ta ni mo gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ tí mo níláti dá a pada fún un?Kò sí olúwarẹ̀ ní gbogbo ayé.

12. “N kò ní yé sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ̀ rẹ̀,tabi nípa agbára rẹ̀ tabi dídára ìdúró rẹ̀.

Ka pipe ipin Jobu 41