Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 41:19-26 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ahọ́n iná ń yọ lẹ́nu rẹ̀ bí iná tí ń ta jáde,bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n iná ń yọ lálá.

20. Èéfín ń jáde ní imú rẹ̀,bíi ti ìkòkò gbígbóná ati ìgbẹ́ tí ń jó.

21. Èémí tí ó ń mí jáde dàbí ògúnná,ahọ́n iná ń yọ ní ẹnu rẹ̀.

22. Kìkì agbára ni ọrùn rẹ̀,ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀.

23. Ìṣẹ́po ẹran ara rẹ̀ lẹ̀ pọ̀ mọ́ ara wọn,wọ́n lẹ̀ pọ̀, wọn kò sì ṣe é ṣí.

24. Ọkàn rẹ̀ le bí òkúta,ó le ju ọlọ lọ.

25. Bí ó bá dìde, ẹ̀rù á ba àwọn alágbára,wọn á bì sẹ́yìn, wọn á ṣubú lé ara wọn lórí.

26. Bí idà tilẹ̀ bá a, kò ràn án,bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀kọ̀, ati ọfà, ati ẹ̀sín.

Ka pipe ipin Jobu 41