Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 40:15-24 BIBELI MIMỌ (BM)

15. “Wo Behemoti, ẹran ńlá inú omi,tí mo dá gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ọ,koríko ni ó ń jẹ bíi mààlúù!

16. Wò ó bí ó ti lágbára tó!Ati irú okun tí awọ inú rẹ̀ ní.

17. Ìrù rẹ̀ dúró ṣánṣán bí igi kedari,gbogbo iṣan itan rẹ̀ dì pọ̀.

18. Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá idẹ,ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí irin.

19. “Ó wà lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí èmi Ọlọrun dá,sibẹ ẹlẹ́dàá rẹ̀ nìkan ló lè pa á.

20. Orí àwọn òkè ni ó ti ń rí oúnjẹ jẹ,níbi tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ ti ń ṣeré.

21. Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lotusi,lábẹ́ ọ̀pá ìyè ninu ẹrẹ̀.

22. Igi lotusi ni ó ń ṣíji bò ó,igi tí ó wà létí odò yí i ká.

23. Kò náání ìgbì omi,kò bẹ̀rù bí odò Jọdani tilẹ̀ ru dé bèbè rẹ̀.

24. Ṣé eniyan lè fi ìwọ̀ mú un?Tabi kí á fi ọ̀kọ̀ lu ihò sí imú rẹ̀?

Ka pipe ipin Jobu 40