11. Fi ibinu rẹ hàn, wo gbogbo àwọn agbéraga,kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
12. Wo gbogbo àwọn agbéraga, kí o sì sọ wọ́n di yẹpẹrẹ,rún àwọn ẹni ibi mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
13. Bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ papọ̀,dì wọ́n ní ìgbèkùn sí ipò òkú.
14. Nígbà náà ni n óo gbà pé,agbára rẹ lè fún ọ ní ìṣẹ́gun.
15. “Wo Behemoti, ẹran ńlá inú omi,tí mo dá gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ọ,koríko ni ó ń jẹ bíi mààlúù!
16. Wò ó bí ó ti lágbára tó!Ati irú okun tí awọ inú rẹ̀ ní.
17. Ìrù rẹ̀ dúró ṣánṣán bí igi kedari,gbogbo iṣan itan rẹ̀ dì pọ̀.