Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 40:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA tún sọ fún Jobu pé,

2. “Ṣé ẹni tí ń bá eniyan rojọ́ lè bá Olodumare rojọ́?Kí ẹni tí ń bá Ọlọrun jiyàn dáhùn.”

3. Nígbà náà ni Jobu dá OLUWA lóhùn, ó ní:

4. “OLUWA, kí ni mo jámọ́,tí n óo fi dá ọ lóhùn?Nítorí náà, mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.

5. Mo ti sọ̀rọ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,n kò sì ní sọ̀rọ̀ mọ́.”

6. Nígbà náà ni OLUWA tún bá Jobu sọ̀rọ̀ láti inú ìjì líle, ó ní,

7. “Múra gírí bí ọkunrin,mo ní ìbéèrè láti bi ọ́, o óo sì dá mi lóhùn.

8. Ṣé o fẹ́ sọ pé mò ń ṣe àìdára ni?O fẹ́ dá mi lẹ́bi kí á lè dá ọ láre?

9. Ṣé o lágbára bí èmi Ọlọrun,àbí o lè sán wàá bí ààrá, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀?

10. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fi ọlá ati ìyìn ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́,kí o sì fi ògo ati ẹwà bo ara rẹ bí aṣọ.

11. Fi ibinu rẹ hàn, wo gbogbo àwọn agbéraga,kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

12. Wo gbogbo àwọn agbéraga, kí o sì sọ wọ́n di yẹpẹrẹ,rún àwọn ẹni ibi mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.

13. Bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ papọ̀,dì wọ́n ní ìgbèkùn sí ipò òkú.

Ka pipe ipin Jobu 40