9. “Ṣé ẹfọ̀n ṣetán láti sìn ọ́?Ṣé yóo wá sùn ní ibùjẹ ẹran rẹ lálẹ́?
10. Ṣé o lè so àjàgà mọ́ ọn lọ́rùn ní poro oko,tabi kí ó máa kọ ebè tẹ̀lé ọ?
11. Ṣé o lè gbẹ́kẹ̀lé e nítorí pé agbára rẹ̀ pọ̀,tabi kí o fi iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ fún un láti ṣe?
12. Ṣé o ní igbagbọ pé yóo pada,ati pé yóo ru ọkà rẹ̀ wá sí ibi ìpakà rẹ?
13. “Ògòǹgò lu ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ninu ọláńlá rẹ̀,ṣugbọn kò lè fò bí ẹyẹ àkọ̀?
14. Ó yé ẹyin rẹ̀ sórí ilẹ̀,kí ooru ilẹ̀ lè mú wọn,
15. ó gbàgbé pé ẹnìkan le tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ kí wọn sì fọ́,ati pé ẹranko ìgbẹ́ lè fọ́ wọn.
16. Ògòǹgò kò náání àwọn ọmọ rẹ̀,ó ń ṣe sí wọn bí ẹni pé kì í ṣe òun ló bí wọn,kò bìkítà bí wahala rẹ̀ tilẹ̀ já sí asán;
17. nítorí pé Ọlọrun kò fún un ní ọgbọ́n ati òye.
18. Ṣugbọn nígbà tí ó bá ṣetán ati sáré,a máa fi ẹṣin ati ẹni tí ó gùn ún ṣe yẹ̀yẹ́.
19. “Ṣé ìwọ ni o fún ẹṣin lágbára,tí o sì fi agbára ṣe gọ̀gọ̀ sí i lọ́rùn?
20. Ṣé ìwọ lò ń mú kí ó máa ta pọ́nún bí eṣú,tí kíké rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù?
21. Ó fẹsẹ̀ walẹ̀ ní àfonífojì,ó yọ̀ ninu agbára rẹ̀,ó sì jáde lọ sí ojú ogun.
22. Kò mọ ẹ̀rù, ọkàn rẹ̀ kì í rẹ̀wẹ̀sì,bẹ́ẹ̀ ni kì í sá fún idà.
23. Ó gbé apó ọfà sẹ́yìn, tí ń mì pẹkẹpẹkẹ, pẹlu ọ̀kọ̀tí ń kọ mànà, ati apata.
24. Ó ń fi ẹnu họlẹ̀ pẹlu ìgboyà ati ìwàǹwára,nígbà tí ipè dún, ara rẹ̀ kò balẹ̀.