Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 39:21-30 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ó fẹsẹ̀ walẹ̀ ní àfonífojì,ó yọ̀ ninu agbára rẹ̀,ó sì jáde lọ sí ojú ogun.

22. Kò mọ ẹ̀rù, ọkàn rẹ̀ kì í rẹ̀wẹ̀sì,bẹ́ẹ̀ ni kì í sá fún idà.

23. Ó gbé apó ọfà sẹ́yìn, tí ń mì pẹkẹpẹkẹ, pẹlu ọ̀kọ̀tí ń kọ mànà, ati apata.

24. Ó ń fi ẹnu họlẹ̀ pẹlu ìgboyà ati ìwàǹwára,nígbà tí ipè dún, ara rẹ̀ kò balẹ̀.

25. Nígbà tí fèrè dún, ó kọ, ‘Hàáà!’Ó ń gbóòórùn ogun lókèèrè,ó ń gbọ́ igbe ọ̀gágun tí ń pàṣẹ.

26. “Ṣé ìwọ lo kọ́ àwòdì bí a ti í fò,tí ó fi na ìyẹ́ rẹ̀ sí ìhà gúsù?

27. Ṣé ìwọ ni o pàṣẹ fún idì láti fò lọ sókè,tabi láti tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sórí òkè gíga?

28. Ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí òkè gíga-gíga,ninu pàlàpálá àpáta.

29. Níbẹ̀ ni ó ti ń ṣọ́ ohun tí yóo pa,ojú rẹ̀ a sì rí i láti òkèèrè réré.

30. Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa mu ẹ̀jẹ̀,ibi tí òkú bá sì wà ni idì máa ń wà.”

Ka pipe ipin Jobu 39