1. “Ǹjẹ́ o mọ ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ?Ṣé o ti ká àgbọ̀nrín mọ́ ibi tí ó ti ń bímọ rí?
2. Ǹjẹ́ o lè ka iye oṣù tí wọ́n fi ń lóyún?Tabi o mọ ìgbà tí wọ́n bímọ?
3. Ǹjẹ́ o mọ ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀,tí wọ́n sì bímọ?
4. Àwọn ọmọ wọn á di alágbára,wọn á dàgbà ninu pápá,wọn á sì lọ, láìpadà wá sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn mọ́.
5. “Ta ló fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ lómìniratí ó sì tú ìdè rẹ̀?
6. Mo fi inú pápá ṣe ilé rẹ̀,ilẹ̀ oníyọ̀ sì di ibùgbé rẹ̀.
7. Ó ń pẹ̀gàn ìdàrúdàpọ̀ inú ìlú ńlá,kò gbọ́ ariwo àwọn tí wọn ń fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ṣiṣẹ́.
8. Ó ń rìn káàkiri àwọn òkè bí ibùjẹ rẹ̀,ó sì ń wá ewéko tútù kiri.
9. “Ṣé ẹfọ̀n ṣetán láti sìn ọ́?Ṣé yóo wá sùn ní ibùjẹ ẹran rẹ lálẹ́?
10. Ṣé o lè so àjàgà mọ́ ọn lọ́rùn ní poro oko,tabi kí ó máa kọ ebè tẹ̀lé ọ?
11. Ṣé o lè gbẹ́kẹ̀lé e nítorí pé agbára rẹ̀ pọ̀,tabi kí o fi iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ fún un láti ṣe?