Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 38:30-41 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Ó sọ omi odò di líle bí òkúta,ojú ibú sì dì bíi yìnyín.

31. “Ṣé o lè fokùn so ìràwọ̀ Pileiadesi,tabi kí o tú okùn ìràwọ̀ Orioni?

32. Ṣé o lè darí àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀, ní àkókò wọn,tabi kí o ṣe atọ́nà ìràwọ̀ Beari ati àwọn ọmọ rẹ̀?

33. Ṣé o mọ àwọn òfin tí ó de ojú ọ̀run?Tabi o lè fìdí wọn múlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?

34. “Ǹjẹ́ o lè pàṣẹ fún ìkùukùu pé,kí ó rọ òjò lé ọ lórí?

35. Ṣé o lè pe mànàmáná pé kí ó wá kí o rán an níṣẹ́kí ó wá bá ọ kí ó wí pé, ‘Èmi nìyí?’

36. Ta ló fi ọgbọ́n sinu ìkùukùuati ìmọ̀ sinu ìrì?

37. Ta ló lè fi ọgbọ́n ká ìkùukùu,tabi tí ó lè tú omi inú ìkùukùu dà sílẹ̀,

38. nígbà tí ilẹ̀ bá gbẹ,tóbẹ́ẹ̀ tí ó dì, tí ó sì le koko?

39. “Ṣé o lè wá oúnjẹ fún kinniun,tabi kí o fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọ̀dọ́ kinniun lọ́rùn,

40. nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ ninu ihò wọn,tabi tí wọ́n ba ní ibùba wọn?

41. Ta ní ń wá oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò,nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá kígbe sí Ọlọrun,tí wọ́n sì ń káàkiri tí wọn ń wá oúnjẹ?

Ka pipe ipin Jobu 38