Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 38:3-11 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Nisinsinyii, múra gírí bí ọkunrin,mo ní ìbéèrè kan láti bí ọ, o óo sì dá mi lóhùn.

4. Níbo lo wà, nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?Bí o bá mọ ìgbà náà, sọ fún mi.

5. Ta ló ṣe ìdíwọ̀n rẹ̀–ṣebí o mọ̀ ọ́n, dá mi lóhùn!Àbí ta ló ta okùn ìwọ̀n sórí rẹ̀?

6. Orí kí ni a gbé ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé,àbí ta ló fi òkúta igun rẹ̀ sọlẹ̀;

7. tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ ń jùmọ̀ kọrin,tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun sì búsáyọ̀?

8. Ta ló tìlẹ̀kùn mọ́ òkun,nígbà tí ó ń ru jáde,

9. tí mo fi awọsanma ṣe ẹ̀wù rẹ̀,tí òkùnkùn biribiri sì jẹ́ ọ̀já ìgbànú rẹ̀,

10. tí mo sì pa ààlà fún un,tí mo sé ìlẹ̀kùn mọ́ ọn,

11. tí mo wí pé, ‘Dúró níhìn-ín, o kò gbọdọ̀ kọjá ibẹ̀,ibí ni ìgbì líle rẹ ti gbọdọ̀ dáwọ́ dúró?’

Ka pipe ipin Jobu 38