Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 38:14-23 BIBELI MIMỌ (BM)

14. A ti yí ayé pada bí amọ̀ tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀,ati bí aṣọ tí a pa láró.

15. A mú ìmọ́lẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹni ibi,a sì ká wọn lápá kò.

16. “Ṣé o ti wọ orísun òkun lọ rí,tabi o ti rìn nísàlẹ̀ ibú rí?

17. Ṣé a ti fi ìlẹ̀kùn ikú hàn ọ́ rí,tabi o ti rí ìlẹ̀kùn òkùnkùn biribiri rí?

18. Ṣé o mọ̀ bí ayé ti tóbi tó?Dá mi lóhùn, bí o bá mọ àwọn nǹkan wọnyi.

19. “Níbo ni ọ̀nà ilé ìmọ́lẹ̀,ibo sì ni ibùgbé òkùnkùn,

20. tí o óo fi lè mú un lọ sí ààyè rẹ̀,tí o fi lè mọ ọ̀nà tí ó lọ sí ilé rẹ̀?

21. Dájúdájú o mọ̀, nítorí pé wọ́n ti bí ọ nígbà náà,o sá ti dàgbà!

22. “Ṣé o ti wọ àwọn ilé ìkẹ́rùsí, tí mò ń kó yìnyín pamọ́ sí rí,tabi ibi tí mò ń kó òjò dídì sí,

23. àní, àwọn tí mo ti pamọ́ de àkókò ìyọnu,fún ọjọ́ ogun ati ọjọ́ ìjà?

Ka pipe ipin Jobu 38