Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 37:11-24 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ó fi omi kún inú ìkùukùu,ìkùukùu sì fọ́n mànàmáná rẹ̀ ká.

12. Wọ́n ń yípo lábẹ́ ìtọ́ni rẹ̀,láti mú gbogbo àṣẹ tí ó pa ṣẹ, lórí ilẹ̀ alààyè.

13. Ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀,bóyá fún àtúnṣe ni, tabi nítorí ilẹ̀ rẹ̀,tabi láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.

14. “Fetí sílẹ̀, ìwọ Jobu,dúró kí o sì ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun.

15. Ǹjẹ́ o mọ bí Ọlọrun ṣe pàṣẹ,tí ó sì mú kí mànàmáná awọsanma tàn?

16. Ǹjẹ́ o mọ̀ bí ó ṣe so awọsanma rọ̀,iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ ni;

17. ìwọ tí ooru mú nígbà tí ayé dákẹ́ rọ́rọ́nítorí pé afẹ́fẹ́ ìhà gúsù kò fẹ́?

18. Ṣé o lè tẹ́ ojú ọ̀run bí ó ti tẹ́ ẹ,kí ó le, kí ó sì dàbí dígí tí ń dán?

19. Kọ́ wa ní ohun tí a lè bá Ọlọrun sọ,a kò lè kó àròyé wa jọ siwaju rẹ̀,nítorí àìmọ̀kan wa.

20. Ṣé kí n sọ fún Ọlọrun pé n ó bá a sọ̀rọ̀ ni?Ta ni yóo fẹ́ kí á gbé òun mì?

21. “Ẹnikẹ́ni kò lè wo ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀runnígbà tí ó bá ń tàn ní awọsanma,nígbà tí afẹ́fẹ́ bá fẹ́ tí ó sì gbá wọn lọ.

22. Láti ìhà àríwá ni Ọlọrun ti yọ,ó fi ọlá ńlá, tí ó bani lẹ́rù, bora bí aṣọ.

23. Àwámárìídìí ni Olodumare–agbára ati ìdájọ́ òtítọ́ rẹ̀ pọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kì í kọ òdodo sílẹ̀.

24. Nítorí náà, gbogbo eniyan bẹ̀rù rẹ̀,kò sì náání àwọn tí wọ́n gbọ́n lójú ara wọn.”

Ka pipe ipin Jobu 37