Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 36:18-33 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ṣọ́ra kí ibinu má baà sọ ọ́ di ẹlẹ́yà,kí títóbi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì mú ọ ṣìnà.

19. Igbe ati agbára rẹ kò lè gbà ọ́ kúrò ninu ìpọ́njú.

20. Má máa dúró, kí o máa retí ọjọ́ alẹ́,nígbà tí à ń pa àwọn eniyan run.

21. Ṣọ́ra kí o má yipada sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀,tí ó wù ọ́ ju ìjìyà lọ.

22. “Wò ó, a gbé OLUWA ga ninu agbára rẹ̀;ta ni olùkọ́ tí ó dàbí rẹ̀?

23. Ta ló ń sọ ohun tí yóo ṣe fún un,tabi kí ó sọ fún un pé, ‘Ohun tí o ṣe yìí kò dára?’

24. Ranti láti gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,tí àwọn eniyan ń kọrin nípa rẹ̀.

25. Gbogbo eniyan ti rí i;àwọn tí wọ́n wà ní òkèèrè ń wò ó.

26. Wò ó, Ọlọrun tóbi lọ́ba, ju ìmọ̀ wa lọ,kò sí ẹni tí ó lè mọ ọjọ́ orí rẹ̀.

27. “Ó fa ìkán omi sókè láti inú ilẹ̀,ó sọ ìkùukùu di òjò,

28. ó sì rọ òjò sílẹ̀ láti ojú ọ̀runsórí ọmọ eniyan lọpọlọpọ.

29. Ta ló mọ bí ó ti tẹ́ ìkùukùu?Tabi bí ó ṣe ń sán ààrá láti inú àgọ́ rẹ̀?

30. Ó fi mànàmáná yí ara rẹ̀ ká,ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀.

31. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè;ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ lọpọlọpọ.

32. Ìkáwọ́ rẹ̀ ni mànàmáná wà,ó sì ń rán ààrá láti sán lu ohun tí ó bá fẹ́.

33. Ìró ààrá ń kéde bíbọ̀ rẹ̀,àwọn ẹran ọ̀sìn sì mọ̀ pé ó súnmọ́ tòsí.

Ka pipe ipin Jobu 36