Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 36:12-24 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ṣugbọn bí wọn kò bá gbọ́ràn,a óo fi idà pa wọ́n,wọn yóo sì kú láìní ìmọ̀.

13. “Àwọn tí kò mọ Ọlọrun fẹ́ràn ibinu,wọn kì í kígbe fún ìrànlọ́wọ́,nígbà tí ó bá fi wọ́n sinu ìdè.

14. Wọn á kú ikú ìtìjú,nígbà tí wọ́n wà ní èwe.

15. A máa lo ìpọ́njú àwọn tí à ń pọ́n lójú láti gbà wọ́n là,a sì máa lo ìdààmú wọn láti ṣí wọn létí.

16. A máa yọ ọ́ kúrò ninu ìpọ́njú,bọ́ sinu ìdẹ̀ra níbi tí kò sí wahala,oúnjẹ tí a gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀ a sì jẹ́ kìkì àdídùn.

17. “Ṣugbọn, ìdájọ́ eniyan burúkú dé bá ọ,ọwọ́ ìdájọ́ ati òdodo sì ti tẹ̀ ọ́.

18. Ṣọ́ra kí ibinu má baà sọ ọ́ di ẹlẹ́yà,kí títóbi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì mú ọ ṣìnà.

19. Igbe ati agbára rẹ kò lè gbà ọ́ kúrò ninu ìpọ́njú.

20. Má máa dúró, kí o máa retí ọjọ́ alẹ́,nígbà tí à ń pa àwọn eniyan run.

21. Ṣọ́ra kí o má yipada sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀,tí ó wù ọ́ ju ìjìyà lọ.

22. “Wò ó, a gbé OLUWA ga ninu agbára rẹ̀;ta ni olùkọ́ tí ó dàbí rẹ̀?

23. Ta ló ń sọ ohun tí yóo ṣe fún un,tabi kí ó sọ fún un pé, ‘Ohun tí o ṣe yìí kò dára?’

24. Ranti láti gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,tí àwọn eniyan ń kọrin nípa rẹ̀.

Ka pipe ipin Jobu 36