Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 36:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Elihu tún tẹ̀síwájú ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní,

2. “Ní sùúrù fún mi díẹ̀, n óo ṣe àlàyé fún ọ,nítorí mo ní ohun kan tí mo fẹ́ gbẹnusọ fún Ọlọrun.

3. N óo gba ìmọ̀ mi láti ọ̀nà jíjìn,n óo sì fi júbà Ẹlẹ́dàá mi, tí ó ní ìmọ̀ òdodo.

4. Nítorí òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ mi;ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ péye ni èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí.

5. “Ọlọrun lágbára, kì í kẹ́gàn ẹnikẹ́ni,agbára ati òye rẹ̀ pọ̀ gan-an.

6. Kì í jẹ́ kí eniyan burúkú ó wà láàyè,ṣugbọn a máa fún ẹni tí ìyà ń jẹ ní ẹ̀tọ́ rẹ̀.

7. Kìí mú ojú kúrò lára àwọn olódodo,ṣugbọn a máa gbé wọn sórí ìtẹ́ pẹlu àwọn ọba,á gbé wọn ga,á sì fi ìdí wọn múlẹ̀ títí lae.

8. Ṣugbọn bí a bá fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n,tí ayé wọn kún fún ìpọ́njú,

9. a máa fi àṣìṣe wọn hàn wọ́n,ati ẹ̀ṣẹ̀ ìgbéraga wọn.

10. Ó fún wọn ní etígbọ̀ọ́,ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀.

11. Bí wọ́n bá gbọ́ràn, tí wọ́n sì sìn ín,wọn yóo lo ọjọ́ ayé wọn pẹlu ìdẹ̀rùn,wọn yóo ṣe ọ̀pọ̀ ọdún ninu ìgbádùn.

Ka pipe ipin Jobu 36