Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 35:2-11 BIBELI MIMỌ (BM)

2. “Jobu, ṣé o rò pé ó tọ̀nà,kí o máa sọ pé, ‘Ọ̀nà mi tọ́ níwájú Ọlọrun?’

3. Kí o tún máa bèèrè pé, ‘Anfaani wo ni mo ní?Tabi kí ni mo fi sàn ju ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀ lọ?’

4. N óo dá ìwọ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lóhùn.

5. Gbójú sókè kí o wo ojú ọ̀run,ati àwọn ìkùukùu tí ó wà lókè.

6. Bí o bá dẹ́ṣẹ̀, kò ṣe Ọlọrun ní àìrójú,bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bá pọ̀, kò jámọ́ nǹkankan fún un.

7. Bí o bá jẹ́ olódodo,kí ni ó dà fún Ọlọrun,tabi kí ni ó ń rí gbà lọ́wọ́ rẹ?

8. Àwọn eniyan burúkú bíì rẹ, ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ lè pa lára,àwọn ọmọ eniyan ni òdodo rẹ sì lè jẹ́ anfaani fún.

9. “Àwọn eniyan ń kígbe nítorí ọpọlọpọ ìnira,wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́,nítorí àwọn alágbára ń tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.

10. Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó bèèrè pé,‘Níbo ni Ọlọrun Ẹlẹ́dàá mi wà,tíí fún ni ní orin ayọ̀ lóru,

11. ẹni tí ó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ju àwọn ẹranko lọ,Ó sì fún wa ní ọgbọ́n ju àwọn ẹyẹ lọ?’

Ka pipe ipin Jobu 35