Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 34:23-31 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Nítorí Ọlọrun kò nílò láti yan àkókò kan fún ẹnikẹ́ni,láti wá siwaju rẹ̀ fún ìdájọ́.

24. Á pa àwọn alágbára run láìṣe ìwádìí wọn,á sì fi àwọn ẹlòmíràn dípò wọn.

25. Nítorí pé ó mọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn,á bì wọ́n ṣubú lóru, wọn á sì parun.

26. Á máa jẹ wọ́n níyà ní gbangba,nítorí ìwà ibi wọn.

27. Nítorí pé wọ́n kọ̀ láti tẹ̀lé e,wọn kò náání ọ̀nà rẹ̀ kankan,

28. wọ́n ń jẹ́ kí àwọn talaka máa kígbe sí Ọlọrun,a sì máa gbọ́ igbe àwọn tí a ni lára.

29. “Bí Ọlọrun bá dákẹ́,ta ló lè bá a wí?Nígbà tí ó bá fi ojú pamọ́,orílẹ̀-èdè tabi eniyan wo ló lè rí i?

30. Kí ẹni ibi má baà lè ṣe àkóso,kí ó má baà kó àwọn eniyan sinu ìgbèkùn.

31. “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tíì sọ fún Ọlọrun pé,‘Mo ti jìyà rí, n kò sì ní gbẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

Ka pipe ipin Jobu 34