1. Elihu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní,
2. “Ẹ gbọ́rọ̀ mi, ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n,ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ ní ìmọ̀,
3. nítorí bí ahọ́n ti í máa ń tọ́ oúnjẹ wò,bẹ́ẹ̀ ni etí náà lè máa tọ́ ọ̀rọ̀ wò
4. Ẹ jẹ́ kí á yan ohun tí ó tọ́,kí á jọ jíròrò ohun tí ó dára láàrin ara wa.
5. Jobu sọ pé òun kò jẹ̀bi,ó ní Ọlọrun ni ó kọ̀ tí kò dá òun láre.
6. Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun jàre, Ọlọrun ka òun kún òpùrọ́,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò dẹ́ṣẹ̀, ọgbẹ́ òun kò ṣe é wòsàn.
7. “Ta ló dàbí Jobu,tí ń kẹ́gàn Ọlọrun nígbà gbogbo,
8. tí ó ń bá àwọn aṣebi kẹ́gbẹ́,tí ó sì ń bá àwọn eniyan burúkú rìn?
9. Nítorí ó ń sọ pé, ‘Kò sí èrè kankan,ninu ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun.’
10. “Nítorí náà ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin olóye,Ọlọrun kì í ṣe ibi,Olodumare kì í ṣe ohun tí kò tọ́.
11. Nítorí a máa san ẹ̀san fún eniyan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ati gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀.
12. Nítòótọ́, Ọlọrun kì í ṣe ibi,bẹ́ẹ̀ ni Olodumare kì í dájọ́ èké.
13. Ta ló fi í ṣe alákòóso ayé,ta ló sì fi jẹ olórí gbogbo ayé?
14. Bí Ọlọrun bá gba ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,tí ó sì gba èémí rẹ̀ pada sọ́dọ̀,
15. gbogbo eniyan ni yóo ṣègbé,tí wọn yóo sì pada di erùpẹ̀.