Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 33:25-32 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Jẹ́ kí àwọ̀ rẹ̀ jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde,kí agbára rẹ̀ sì pada dàbí ti ìgbà ọ̀dọ́;

26. nígbà náà eniyan óo gbadura sí Ọlọrun,Ọlọrun óo sì gbọ́ adura rẹ̀.Eniyan óo wá fi ayọ̀ wá siwaju Ọlọrun,yóo sì ròyìn ìgbàlà Ọlọrun fún gbogbo aráyé

27. Yóo wá sọ gbangba níwájú àwọn eniyan pé,‘Mo ti ṣẹ̀, mo sì ti yí ẹ̀tọ́ po,ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ mí níyà ẹ̀ṣẹ̀ mi.

28. Ó ti ra ọkàn mi pada kúrò lọ́wọ́ isà òkú,mo sì wà láàyè.’

29. “Wò ó, Ọlọrun a máa ṣe nǹkan wọnyi léraléra fún eniyan,lẹẹmeji tabi lẹẹmẹta,

30. láti lè gba ọkàn rẹ̀ là lọ́wọ́ ikú,kí ó lè wà láàyè.

31. “Gbọ́, ìwọ Jobu, farabalẹ̀,dákẹ́ kí o lè gbọ́ ohun tí n óo sọ.

32. Bí o bá ní ohunkohun láti sọ, dá mi lóhùn;sọ̀rọ̀, nítorí pé mo fẹ́ dá ọ láre ni.

Ka pipe ipin Jobu 33