Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 33:10-24 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Sibẹ Ọlọrun wá ẹ̀sùn sí ọ lẹ́sẹ̀,ó sọ ọ́ di ọ̀tá rẹ̀,

11. ó kan ààbà mọ́ ọ lẹ́sẹ̀,ó sì ń ṣọ́ ìrìn rẹ.

12. “Jobu, n óo dá ọ lóhùn,nítorí pé bí o ti wí yìí, bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí.Ọlọrun ju eniyan lọ.

13. Kí ló dé tí ò ń fi ẹ̀sùn kàn ánpé kò ní fèsì kankan sí ọ̀rọ̀ rẹ?

14. Nítorí Ọlọrun sọ̀rọ̀ bákan, ó tún tún un sọ bámìíràn,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yé.

15. Ninu àlá, lójú ìran ní ààrin òru,nígbà tí eniyan bá sun oorun àsùnwọra, lórí ibùsùn wọn,

16. Ọlọrun a máa ṣí wọn létí,a máa kìlọ̀ fún wọn, a sì máa dẹ́rùbà wọ́n,

17. kí ó lè dá wọn lẹ́kun ìṣe wọn,kí ó lè gba ìgbéraga lọ́wọ́ wọn;

18. kí ó lè yọ ọkàn eniyan kúrò ninu ọ̀fìn ìparun,kí ó má baà kú ikú idà.

19. “OLUWA a máa fi ìrora jẹ eniyan níyà lórí ibùsùn rẹ̀;a sì máa kó ìnira bá egungun rẹ̀.

20. Tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu rẹ̀ yóo kọ oúnjẹ,oúnjẹ àdídùn óo sì rùn sí i.

21. Eniyan á rù hangangan,wọn a sì fẹ́rẹ̀ lè máa ka egungun rẹ̀.

22. Ọkàn rẹ̀ á súnmọ́ ibojì,ẹ̀mí rẹ̀ a sì súnmọ́ àwọn iranṣẹ ikú.

23. Bí angẹli kan bá wà pẹlu rẹ̀,tí ó wà fún un bí onídùúró,àní, ọ̀kan láàrin ẹgbẹrun,tí yóo sọ ohun tí ó tọ́ fún un,

24. tí yóo ṣàánú rẹ̀, tí yóo sì wí pé,‘Ẹ gbà á sílẹ̀, ẹ má jẹ́ kí ó lọ sinu ibojì,mo ti rí ìràpadà kan dípò rẹ̀.’

Ka pipe ipin Jobu 33