Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 33:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Jobu, tẹ́tí sílẹ̀ nisinsinyii kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.

2. Wò ó! Mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀,ọ̀rọ̀ sì pọ̀ tí mo fẹ́ sọ.

3. Òtítọ́ inú ni mo fi fẹ́ sọ̀rọ̀,ohun tí mo mọ̀ pé òdodo ni ni mo sì fẹ́ sọ.

4. Ẹ̀mí Ọlọrun ni ó dá mi,èémí Olodumare ni ó sì fún mi ní ìyè.

5. “Bí o bá lè dá mi lóhùn, dáhùn.Ro ohun tí o fẹ́ sọ dáradára,kí o sì múra láti wí àwíjàre.

6. Wò ó, bákan náà ni èmi pẹlu rẹ rí lójú Ọlọrun,amọ̀ ni a fi mọ èmi náà.

7. Má jẹ́ kí ẹ̀rù mi bà ọ́,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní le kankan mọ́ ọ.

8. “Lóòótọ́, o ti sọ̀rọ̀ ní etígbọ̀ọ́ mi,mo sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.

9. O ní o mọ́, o kò ní ẹ̀ṣẹ̀,ara rẹ mọ́ o kò sì ṣe àìdára kankan.

10. Sibẹ Ọlọrun wá ẹ̀sùn sí ọ lẹ́sẹ̀,ó sọ ọ́ di ọ̀tá rẹ̀,

11. ó kan ààbà mọ́ ọ lẹ́sẹ̀,ó sì ń ṣọ́ ìrìn rẹ.

12. “Jobu, n óo dá ọ lóhùn,nítorí pé bí o ti wí yìí, bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí.Ọlọrun ju eniyan lọ.

13. Kí ló dé tí ò ń fi ẹ̀sùn kàn ánpé kò ní fèsì kankan sí ọ̀rọ̀ rẹ?

14. Nítorí Ọlọrun sọ̀rọ̀ bákan, ó tún tún un sọ bámìíràn,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yé.

15. Ninu àlá, lójú ìran ní ààrin òru,nígbà tí eniyan bá sun oorun àsùnwọra, lórí ibùsùn wọn,

Ka pipe ipin Jobu 33