Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 31:33-40 BIBELI MIMỌ (BM)

33. bí mo bá fi ẹ̀ṣẹ̀ mi pamọ́ fún eniyan,tí mo sì dé àìdára mi mọ́ra,

34. nítorí pé mò ń bẹ̀rù ọpọlọpọ eniyan,ẹ̀gàn ìdílé sì ń dẹ́rùbà mí,tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi dákẹ́, tí n kò sì jáde síta.

35. Ha! Ǹ bá rí ẹni gbọ́ tèmi!(Mo ti tọwọ́ bọ̀wé,kí Olodumare dá mi lóhùn!)Ǹ bá lè ní àkọsílẹ̀ ẹ̀sùn tí àwọn ọ̀tá fi kàn mí!

36. Dájúdájú, ǹ bá gbé e lé èjìká mi,ǹ bá fi dé orí bí adé;

37. ǹ bá sọ gbogbo ìgbésẹ̀ mi fún Ọlọrun,ǹ bá bá a sọ̀rọ̀ bí ìjòyè.

38. “Bí ilẹ̀ mi bá kígbe ẹ̀san lé mi lórí,tí àwọn poro oko mi sì ń sọkún;

39. tí mo bá jẹ ninu ìkórè ilẹ̀ náà láìsanwó rẹ̀,tabi tí mo sì ṣe ikú pa ẹni tí ó ni ín,

40. kí ẹ̀gún hù lórí ilẹ̀ náà dípò ọkà,kí koríko hù dípò ọkà baali.”Ọ̀rọ̀ Jobu parí síhìn-ín.

Ka pipe ipin Jobu 31