Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 31:29-39 BIBELI MIMỌ (BM)

29. “Bí mo bá yọ̀ nítorí ìparun ẹni tí ó kórìíra mi,tabi kí inú mi dùn nígbà tí ohun burúkú bá ṣẹlẹ̀ sí i.

30. (N kò fi ẹnu mi ṣẹ̀kí n gbé e ṣépè pé kí ó lè kú);

31. bí àwọn tí wọn ń gbé inú àgọ́ mi kò bá wí pé,‘Ta ló kù tí kò tíì yó?’

32. (Kò sí àlejò tí ń sun ìta gbangba,nítorí ìlẹ̀kùn ilé mi ṣí sílẹ̀ fún àwọn arìnrìnàjò);

33. bí mo bá fi ẹ̀ṣẹ̀ mi pamọ́ fún eniyan,tí mo sì dé àìdára mi mọ́ra,

34. nítorí pé mò ń bẹ̀rù ọpọlọpọ eniyan,ẹ̀gàn ìdílé sì ń dẹ́rùbà mí,tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi dákẹ́, tí n kò sì jáde síta.

35. Ha! Ǹ bá rí ẹni gbọ́ tèmi!(Mo ti tọwọ́ bọ̀wé,kí Olodumare dá mi lóhùn!)Ǹ bá lè ní àkọsílẹ̀ ẹ̀sùn tí àwọn ọ̀tá fi kàn mí!

36. Dájúdájú, ǹ bá gbé e lé èjìká mi,ǹ bá fi dé orí bí adé;

37. ǹ bá sọ gbogbo ìgbésẹ̀ mi fún Ọlọrun,ǹ bá bá a sọ̀rọ̀ bí ìjòyè.

38. “Bí ilẹ̀ mi bá kígbe ẹ̀san lé mi lórí,tí àwọn poro oko mi sì ń sọkún;

39. tí mo bá jẹ ninu ìkórè ilẹ̀ náà láìsanwó rẹ̀,tabi tí mo sì ṣe ikú pa ẹni tí ó ni ín,

Ka pipe ipin Jobu 31