Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 31:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Mo ti bá ojú mi dá majẹmu;n óo ṣe wá máa wo wundia?

2. Kí ni yóo jẹ́ ìpín mi lọ́dọ̀ Ọlọrun lókè?Kí ni ogún mi lọ́dọ̀ Olodumare?

3. Ṣebí jamba a máa bá àwọn alaiṣododo,àjálù a sì máa dé bá àwọn oníṣẹ́-ẹ̀ṣẹ̀.

4. Ṣebí Ọlọrun mọ ọ̀nà mi,ó sì mọ ìrìn mi.

5. Bí mo bá rìn ní ọ̀nà aiṣododo,tí mo sì yára láti sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn,

6. (kí Ọlọrun gbé mi ka orí ìwọ̀n tòótọ́,yóo sì rí i pé olóòótọ́ ni mí!)

7. Bí mo bá ti yí ẹsẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tààrà,tí mò ń ṣe ojúkòkòrò,tí ọwọ́ mi kò sì mọ́,

8. jẹ́ kí ẹlòmíràn kórè oko mi,kí o sì fa ohun ọ̀gbìn mi tu.

9. “Bí ọkàn mi bá fà sí obinrin olobinrin,tabi kí n máa pẹ́ kọ̀rọ̀ lẹ́nu ọ̀nà aládùúgbò mi;

10. jẹ́ kí iyawo mi máa se oúnjẹ fún ẹlòmíràn,kí ẹlòmíràn sì máa bá a lòpọ̀.

11. Nítorí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú jù,ẹ̀ṣẹ̀ tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún.

Ka pipe ipin Jobu 31