Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 3:8-17 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Kí àwọn tí wọ́n ń fi ọjọ́ gégùn-ún fi gégùn-ún,àní àwọn tí wọ́n lè fi àṣẹ rú Lefiatani sókè.

9. Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ rẹ̀ ṣókùnkùn,kí ìrètí rẹ̀ fún ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́ já sí òfo,kí ó má rí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ mọ́;

10. nítorí pé kò sé inú ìyá minígbà tí ó fẹ́ bí mi,bẹ́ẹ̀ ni kò sì mú ibi kúrò lọ́nà mi.

11. “Kí ló dé tí n kò kúnígbà tí ìyá mi ń rọbí lọ́wọ́, tí ó fẹ́ bí mi,tabi kí n kú, lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n bí mi?

12. Kí ló dé tí ìyá mi gbé mi lẹ́sẹ̀?Kí ló dé tí ó fi fún mi lọ́mú?

13. Ǹ bá ti dùbúlẹ̀,ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́;ǹ bá ti sùn,ǹ bá sì ti máa sinmi

14. pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìgbìmọ̀ àgbáyé, tí wọ́n ti sùn,àwọn tí wọ́n tún àlàpà kọ́ fún ara wọn;

15. tabi pẹlu àwọn ọmọ aládé tí wọ́n ní wúrà,tí fadaka sì kún ilé wọn.

16. Tabi kí n rí bí ọmọtí a bí ní ọjọ́ àìpé,tí a bò mọ́lẹ̀ láì tíì lajú sáyé.

17. Níbi tí àwọn oníṣẹ́ ibi kò ti lágbára mọ́,tí àwọn tí gbogbo nǹkan ti sú gbé ń sinmi.

Ka pipe ipin Jobu 3