Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 3:2-12 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ó ní:

3. “Ègún ni fún ọjọ́ tí wọ́n bí mi,ati alẹ́ tí wọ́n lóyún mi.

4. Jẹ́ kí ọjọ́ náà ṣókùnkùn biribiri!Kí Ọlọrun má ṣe ka ọjọ́ náà sí,kí ìmọ́lẹ̀ má ṣe tàn sí i mọ́.

5. Ṣe é ní ọjọ́ ìṣúdudu,ati òkùnkùn biribiri.Kí ìkùukùu ṣíji bò ó,kí òkùnkùn sì dẹ́rù bà á.

6. Kí òkùnkùn ṣú bo alẹ́ ọjọ́ náà biribiri,kí á yọ ọ́ kúrò ninu àwọn ọjọ́tí ó wà ninu ọdún,kí á má sì ṣe kà á kúnàwọn ọjọ́ tí wọ́n wà ninu oṣù.

7. Kí alẹ́ ọjọ́ náà di òfo,kí á má ṣe gbọ́ ìró ayọ̀ ninu rẹ̀ mọ́.

8. Kí àwọn tí wọ́n ń fi ọjọ́ gégùn-ún fi gégùn-ún,àní àwọn tí wọ́n lè fi àṣẹ rú Lefiatani sókè.

9. Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ rẹ̀ ṣókùnkùn,kí ìrètí rẹ̀ fún ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́ já sí òfo,kí ó má rí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ mọ́;

10. nítorí pé kò sé inú ìyá minígbà tí ó fẹ́ bí mi,bẹ́ẹ̀ ni kò sì mú ibi kúrò lọ́nà mi.

11. “Kí ló dé tí n kò kúnígbà tí ìyá mi ń rọbí lọ́wọ́, tí ó fẹ́ bí mi,tabi kí n kú, lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n bí mi?

12. Kí ló dé tí ìyá mi gbé mi lẹ́sẹ̀?Kí ló dé tí ó fi fún mi lọ́mú?

Ka pipe ipin Jobu 3