Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 3:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí ó yá, Jobu bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó fi ọjọ́ ìbí ara rẹ̀ bú.

2. Ó ní:

3. “Ègún ni fún ọjọ́ tí wọ́n bí mi,ati alẹ́ tí wọ́n lóyún mi.

4. Jẹ́ kí ọjọ́ náà ṣókùnkùn biribiri!Kí Ọlọrun má ṣe ka ọjọ́ náà sí,kí ìmọ́lẹ̀ má ṣe tàn sí i mọ́.

5. Ṣe é ní ọjọ́ ìṣúdudu,ati òkùnkùn biribiri.Kí ìkùukùu ṣíji bò ó,kí òkùnkùn sì dẹ́rù bà á.

6. Kí òkùnkùn ṣú bo alẹ́ ọjọ́ náà biribiri,kí á yọ ọ́ kúrò ninu àwọn ọjọ́tí ó wà ninu ọdún,kí á má sì ṣe kà á kúnàwọn ọjọ́ tí wọ́n wà ninu oṣù.

7. Kí alẹ́ ọjọ́ náà di òfo,kí á má ṣe gbọ́ ìró ayọ̀ ninu rẹ̀ mọ́.

Ka pipe ipin Jobu 3