Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 29:18-25 BIBELI MIMỌ (BM)

18. “Nígbà náà, mo rò pé, n óo gbòó, n óo tọ̀ọ́ láyé,ati pé inú ilé mi ni n óo sì kú sí.

19. Mo ta gbòǹgbò lọ síbi omi,ìrì sì ń sẹ̀ sí ẹ̀ka mi ní alaalẹ́.

20. Ọlá hàn lára mi,agbára mi sì ń di titun nígbà gbogbo.

21. Àwọn eniyan á dákẹ́ jẹ́ẹ́, wọn á farabalẹ̀ gbọ́ tèmi,wọ́n sì ń gba ìmọ̀ràn mi pẹlu.

22. Lẹ́yìn tí mo bá ti sọ̀rọ̀ tán,ẹnikẹ́ni kì í tún sọ̀rọ̀ mọ́,ọ̀rọ̀ mi a máa wọ̀ wọ́n lára.

23. Wọ́n ń retí mi,bí ẹni retí òjò àkọ́rọ̀.

24. Mo rẹ́rìn-ín sí wọn nígbà tí wọn ń ṣiyèméjì,wọn kò sì lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi.

25. Mo jókòó bí ọba, mò ń tọ́ wọn sọ́nà,mo dàbí ọba láàrin àwọn ọmọ ogun rẹ̀,bí olùtùnú fún oníròbìnújẹ́.

Ka pipe ipin Jobu 29