Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 29:10-20 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Àwọn olórí á panumọ́,ahọ́n wọn á lẹ̀ mọ́ wọn lẹ́nu.

11. Àwọn tí wọ́n gbọ́ nípa mi, ń pè mí ní ẹni ibukun,àwọn tí wọ́n rí mi ń kan sáárá sí mi.

12. Nítorí pé mò ń ran àwọn aláìní tí ń ké lọ́wọ́,ati àwọn aláìníbaba tí wọn kò ní olùrànlọ́wọ́.

13. Ìre àwọn tí ń kú lọ mọ́ mi,mo sì mú kí opó kọrin ayọ̀.

14. Mo fi òdodo bora bí aṣọ,ìdájọ́ òtítọ́ dàbí ẹ̀wù ati adé mi.

15. Mo jẹ́ ojú fún afọ́jú,ati ẹsẹ̀ fún arọ.

16. Mo jẹ́ baba fún talaka,mo gba ẹjọ́ àlejò rò.

17. Mo ṣẹ́ ẹni ibi lápá,mo gba ẹni tí ó mú sílẹ̀.

18. “Nígbà náà, mo rò pé, n óo gbòó, n óo tọ̀ọ́ láyé,ati pé inú ilé mi ni n óo sì kú sí.

19. Mo ta gbòǹgbò lọ síbi omi,ìrì sì ń sẹ̀ sí ẹ̀ka mi ní alaalẹ́.

20. Ọlá hàn lára mi,agbára mi sì ń di titun nígbà gbogbo.

Ka pipe ipin Jobu 29