Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 29:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jobu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé,

2. “Ìbá jẹ́ tún rí fún mi, bí ìgbà àtijọ́,nígbà tí Ọlọrun ń tọ́jú mi;

3. nígbà tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn sí mi lórí,tí mo kọjá ninu òkùnkùn pẹlu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀;

4. kí ó tún rí fún mi bí ìgbà tí ara dẹ̀ mí,nígbà tí ìrẹ́pọ̀ wà láàrin Ọlọrun ati ìdílé mi;

5. tí Olodumare wà pẹlu mi,tí gbogbo àwọn ọmọ mi yí mi ká;

6. tí mò ń rí ọpọlọpọ wàrà lára àwọn ẹran ọ̀sìn mi,ati ọpọlọpọ òróró lára igi olifi tí ń dàgbà láàrin òkúta!

7. Nígbà tí mo lọ sí ẹnubodè ìlú,tí mo jókòó ní gbàgede,

8. tí àwọn ọdọmọkunrin bá rí mi, wọn á bìlà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan,àwọn àgbà á sì dìde dúró;

9. àwọn ìjòyè á dákẹ́ rọ́rọ́,wọn á fi ọwọ́ bo ẹnu wọn.

10. Àwọn olórí á panumọ́,ahọ́n wọn á lẹ̀ mọ́ wọn lẹ́nu.

11. Àwọn tí wọ́n gbọ́ nípa mi, ń pè mí ní ẹni ibukun,àwọn tí wọ́n rí mi ń kan sáárá sí mi.

Ka pipe ipin Jobu 29