Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 28:5-14 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ní ti ilẹ̀, inú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde,ṣugbọn lábẹ́ rẹ̀, ó dàbí ẹnipé iná ń yí i po,ó gbóná janjan.

6. Safire ń bẹ ninu àwọn òkúta rẹ̀,wúrà sì ni erùpẹ̀ rẹ̀.

7. Ẹyẹ àṣá kò mọ ipa ọ̀nà ibẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ojú gúnnugún kò tó o.

8. Àwọn ẹranko onigbeeraga kò tíì tẹ ojú ọ̀nà náà,kinniun kò sì tíì gba ibẹ̀ kọjá rí.

9. “Eniyan á dá ọwọ́ rẹ̀ lé òkúta akọ, á gbẹ́ ẹ,á sì hú òkè ńlá tìdítìdí.

10. Á gbẹ́ ihò sinu àpáta,ojú rẹ̀ a sì tó àwọn ìṣúra iyebíye.

11. Á dí orísun àwọn odò,tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò fi lè sun,á sì wá àwọn ohun tí ó pamọ́ jáde.

12. Ṣugbọn níbo ni a ti lè rí ọgbọ́n?Níbo sì ni ìmọ̀ wà?

13. “Ẹnikẹ́ni kò mọ ọ̀nà ibi tí ó wà;bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ilẹ̀ alààyè.

14. Ibú sọ pé, ‘Kò sí ninu mi,’òkun sì ní, ‘Kò sí lọ́dọ̀ mi.’

Ka pipe ipin Jobu 28