Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 28:15-28 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Wúrà iyebíye kò lè rà á,fadaka kò sì ṣe é díwọ̀n iye rẹ̀.

16. A kò lè fi wúrà Ofiri díwọ̀n iye rẹ̀,tabi òkúta onikisi tabi safire tí wọ́n jẹ́ òkúta olówó iyebíye.

17. Ọgbọ́n níye lórí ju wúrà ati dígí lọ,a kò lè fi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà dáradára ṣe dípò rẹ̀.

18. Kí á má tilẹ̀ sọ ti iyùn tabi Kristali,ọgbọ́n ní iye lórí ju òkúta Pali lọ.

19. A kò lè fi wé òkúta topasi láti ilẹ̀ Etiopia,tabi kí á fi ojúlówó wúrà rà á.

20. “Níbo ni ọgbọ́n ti ń wá;níbo sì ni ìmọ̀ wà?

21. Ó pamọ́ lójú gbogbo ẹ̀dá alààyè,ati lójú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.

22. Ìparun ati ikú jẹ́wọ́ pé,‘Àhesọ ni ohun tí a gbọ́ nípa rẹ̀.’

23. “Ọlọrun nìkan ló mọ ọ̀nà rẹ̀,òun nìkan ló mọ ibùjókòó rẹ̀.

24. Nítorí pé ó ń wo gbogbo ayé,ó sì ń rí ohun gbogbo tí ó wà lábẹ́ ọ̀run.

25. Nígbà tí ó fún afẹ́fẹ́ ní agbára,tí ó sì ṣe ìdíwọ̀n omi,

26. nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò,tí ó sì lànà fún mànàmáná.

27. Lẹ́yìn náà ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde,ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, ó sì dán an wò.

28. Nígbà náà ni ó sọ fún eniyan pé,‘Wò ó, ìbẹ̀rù OLUWA ni ọgbọ́n,kí á yẹra fún ibi sì ni ìmọ̀.’ ”

Ka pipe ipin Jobu 28