Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 28:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Dájúdájú, ibìkan wà tí wọ́n ti ń wa fadaka,ibìkan sì wà tí wọ́n ti ń yọ́ wúrà.

2. Inú ilẹ̀ ni a ti ń wa irin,a sì ń yọ́ idẹ lára òkúta.

3. Eniyan á sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀,a sì ṣe àwárí irin,ninu ọ̀gbun ati òkùnkùn biribiri.

4. Wọn á gbẹ́ kòtò ninu àfonífojì,níbi tí ó jìnnà sí ibi tí eniyan ń gbé,àwọn arìnrìnàjò á gbàgbé wọn,wọn á takété sí àwọn eniyan, wọn á sì máa rọ̀ dirodiro sọ́tùn-ún sósì.

5. Ní ti ilẹ̀, inú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde,ṣugbọn lábẹ́ rẹ̀, ó dàbí ẹnipé iná ń yí i po,ó gbóná janjan.

6. Safire ń bẹ ninu àwọn òkúta rẹ̀,wúrà sì ni erùpẹ̀ rẹ̀.

7. Ẹyẹ àṣá kò mọ ipa ọ̀nà ibẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ojú gúnnugún kò tó o.

8. Àwọn ẹranko onigbeeraga kò tíì tẹ ojú ọ̀nà náà,kinniun kò sì tíì gba ibẹ̀ kọjá rí.

9. “Eniyan á dá ọwọ́ rẹ̀ lé òkúta akọ, á gbẹ́ ẹ,á sì hú òkè ńlá tìdítìdí.

Ka pipe ipin Jobu 28