Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 27:15-23 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Àwọn ọmọ tí wọn bá gbẹ̀yìn rẹ̀,àjàkálẹ̀ àrùn ni yóo pa wọ́n,àwọn opó wọn kò sì ní ṣọ̀fọ̀ wọn.

16. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń kó fadaka jọ bí erùpẹ̀,tí ó sì to aṣọ jọ bí amọ̀;

17. olódodo ni yóo wọ aṣọ tí ó bá kó jọ,àwọn aláìṣẹ̀ ni yóo pín fadaka rẹ̀.

18. Ilé tí ó kọ́ dàbí òwú aláǹtakùn,àní bí àgọ́ àwọn tí wọn ń ṣọ́nà.

19. A ti máa wọlé sùn pẹlu ọrọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn kò ní rí bẹ́ẹ̀ fún un mọ́.Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ yóo ti fò lọ.

20. Ìwárìrì á bò ó mọ́lẹ̀ bí ìkún omi,ní alẹ́, ìjì líle á gbé e lọ.

21. Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn á fẹ́ ẹ sókè,á sì gbé e lọ,á gbá a kúrò ní ipò rẹ̀.

22. Á dìgbò lù ú láìṣàánú rẹ̀,á sá lọ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.

23. Ọlọrun á pàtẹ́wọ́ lé e lórí,á sì pòṣé sí i láti ibi tí ó wà.

Ka pipe ipin Jobu 27