Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 27:13-22 BIBELI MIMỌ (BM)

13. “Ìpín ẹni ibi láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìyí,òun ni ogún tí àwọn aninilára ń rí gbà lọ́dọ̀ Olodumare:

14. Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá ń pọ̀ sí i,kí ogun baà lè pa wọ́n ni,oúnjẹ kò sì ní ká wọn lẹ́nu.

15. Àwọn ọmọ tí wọn bá gbẹ̀yìn rẹ̀,àjàkálẹ̀ àrùn ni yóo pa wọ́n,àwọn opó wọn kò sì ní ṣọ̀fọ̀ wọn.

16. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń kó fadaka jọ bí erùpẹ̀,tí ó sì to aṣọ jọ bí amọ̀;

17. olódodo ni yóo wọ aṣọ tí ó bá kó jọ,àwọn aláìṣẹ̀ ni yóo pín fadaka rẹ̀.

18. Ilé tí ó kọ́ dàbí òwú aláǹtakùn,àní bí àgọ́ àwọn tí wọn ń ṣọ́nà.

19. A ti máa wọlé sùn pẹlu ọrọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn kò ní rí bẹ́ẹ̀ fún un mọ́.Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ yóo ti fò lọ.

20. Ìwárìrì á bò ó mọ́lẹ̀ bí ìkún omi,ní alẹ́, ìjì líle á gbé e lọ.

21. Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn á fẹ́ ẹ sókè,á sì gbé e lọ,á gbá a kúrò ní ipò rẹ̀.

22. Á dìgbò lù ú láìṣàánú rẹ̀,á sá lọ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.

Ka pipe ipin Jobu 27