Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 27:10-15 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ǹjẹ́ yóo ní inú dídùn sí Olodumare?Ǹjẹ́ yóo máa ké pe Ọlọrun nígbà gbogbo?

11. “N óo kọ yín ní ìmọ̀ agbára Ọlọ́run;n kò sì ní fi ohun tíí ṣe ti Olodumare pamọ́.

12. Wò ó! Gbogbo yín ni ẹ ti fojú yín rí i,kí ló wá dé tí gbogbo yín fí ń sọ ìsọkúsọ?”

13. “Ìpín ẹni ibi láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìyí,òun ni ogún tí àwọn aninilára ń rí gbà lọ́dọ̀ Olodumare:

14. Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá ń pọ̀ sí i,kí ogun baà lè pa wọ́n ni,oúnjẹ kò sì ní ká wọn lẹ́nu.

15. Àwọn ọmọ tí wọn bá gbẹ̀yìn rẹ̀,àjàkálẹ̀ àrùn ni yóo pa wọ́n,àwọn opó wọn kò sì ní ṣọ̀fọ̀ wọn.

Ka pipe ipin Jobu 27