Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 27:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jobu tún dáhùn pé,

2. “Mo fi Ọlọrun tí ó gba ẹ̀tọ́ mi búra,mo fi Olodumare tí ó mú kí ọkàn mi bàjẹ́ ṣẹ̀rí,

3. níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè,tí mo sì ń mí,

4. n kò ní fi ẹnu mi purọ́,ahọ́n mi kò sì ní sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

5. Kí á má rí i, n kò jẹ́ pè yín ní olóòótọ́;títí di ọjọ́ ikú mi ni n óo dúró lórí ọ̀rọ̀ mi,pé mo wà lórí àre.

6. Mo dúró lórí òdodo mi láìyẹsẹ̀,ọkàn mi kò ní dá mi lẹ́bi,títí n óo fi kú.

7. “Kí ó rí fún ọ̀tá mi gẹ́gẹ́ bí í ti í rí fún ẹni ibi,kí ó sì rí fún ẹni tí ó dojú kọ mí bí í ti í rí fún alaiṣododo.

8. Ìrètí wo ni ẹni tí kò mọ Ọlọrun ní nígbà tí Ọlọrun bá pa á run,tí Ọlọrun sì gba ẹ̀mí rẹ̀?

9. Ǹjẹ́ Ọlọrun yóo gbọ́ igbe rẹ̀,nígbà tí ìyọnu bá dé bá a?

Ka pipe ipin Jobu 27