Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 24:14-25 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Bí ilẹ̀ bá ṣú, apànìyàn á dìde,kí ó lè pa talaka ati aláìní,a sì dàbí olè ní òru.

15. Alágbèrè pàápàá ń ṣọ́ kí ilẹ̀ ṣú,ó ń wí pé, ‘Kò sí ẹni tí yóo rí mi’;ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀.

16. Lóru, wọn á máa lọ fọ́ ilé kiri,ṣugbọn bí ilẹ̀ bá ti mọ́,wọn á ti ìlẹ̀kùn mọ́rí,wọn kì í rí ìmọ́lẹ̀.

17. Àárọ̀ ni òkùnkùn biribiri jẹ́ fún gbogbo wọn,ọ̀rẹ́ wọn ni òkùnkùn biribiri tí ó bani lẹ́rù.”

18. Sofari dáhùn pé,“O sọ wí pé,‘Ìṣàn omi a máa gbá àwọn ẹni ibi lọ kíákíá;ìpín tiwọn a sì di ìfibú ninu ilẹ̀ náà,ẹnikẹ́ni kìí sì í lọ sinu ọgbà àjàrà wọn láti ṣiṣẹ́ mọ́.

19. Bí ọ̀gbẹlẹ̀ ati ooru ṣe máa ń mú kí omi yìnyín gbẹbẹ́ẹ̀ ni ibojì ṣe ń gbé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mì.

20. Wọn á gbàgbé wọn láàrin ìlú,ẹnikẹ́ni kì í ranti orúkọ wọn mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi ṣe é wó lulẹ̀ bí ìtì igi.’

21. Wọ́n ń jẹ oúnjẹ àgàn tí kò bímọ,wọn kò sì ṣe rere fún opó.

22. Sibẹsibẹ Ọlọrun fi ẹ̀mí gígùn fún alágbára nípa agbára rẹ̀;wọn á gbéra nígbà tí ayé bá sú wọn.

23. Ọlọrun ń dáàbò bò wọ́n, ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́,ó sì ń pa wọ́n mọ́ ni ọ̀nà wọn.

24. A gbé wọn ga fún ìgbà díẹ̀,lẹ́yìn náà, a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,wọn á rọ, wọn á sì rẹ̀ dànù bí ewé,a ké wọn kúrò bí orí ọkà bàbà.

25. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí ẹnìkan já mi nírọ́,kí ó sì fi hàn pé ìsọkúsọ ni mò ń sọ.”

Ka pipe ipin Jobu 24