1. Elifasi ará Temani bá dáhùn pé,
2. “Ǹjẹ́ eniyan lè wúlò fún Ọlọrun?Nítòótọ́, bí eniyan tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ara rẹ̀ ni ó wúlò fún.
3. Ǹjẹ́ jíjẹ́ olódodo rẹ̀ ṣe ohun rere kan fún Olodumare,tabi kí ni èrè rẹ̀ bí ó bá jẹ́ ẹni pípé?
4. Ṣé nítorí pé o bẹ̀rù rẹ̀ ni ó ṣe bá ọ wí,tí ó sì ń dá ọ lẹ́jọ́?
5. Ṣebí ìwà ibi rẹ ló pọ̀;tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lópin?
6. O gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ àwọn arakunrin rẹ láìnídìí,O bọ́ wọn sí ìhòòhò goloto.
7. O kò fún aláàárẹ̀ ní omi mu,o kọ̀ láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ.
8. Ẹni tí ó lágbára gba ilẹ̀,ẹni tí ó lọ́lá sì ń gbé inú rẹ̀.
9. O lé àwọn opó jáde lọ́wọ́ òfo,o sì ṣẹ́ aláìní baba lápá.
10. Nítorí náà ni okùn dídẹ fi yí ọ ká,tí jìnnìjìnnì sì bò ọ́ lójijì.
11. Ìmọ́lẹ̀ rẹ ti di òkùnkùn, o kò ríran,ìgbì omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.
12. “Ṣebí Ọlọrun wà lókè ọ̀runÓ ń wo àwọn ìràwọ̀ nísàlẹ̀àní àwọn tí wọ́n ga jùlọ,bí ó ti wù kí wọ́n ga tó!
13. Sibẹsibẹ ò ń bèèrè pé, ‘Kí ni Ọlọrun mọ̀?’Ṣé ó lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn biribiri?
14. Ìkùukùu tí ó nípọn yí i ká,tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè ríran,ó sì ń rìn ní òfuurufú ojú ọ̀run.
15. “Ṣé ọ̀nà àtijọ́ ni ìwọ óo máa tẹ̀lé;ọ̀nà tí àwọn ẹni ibi rìn?