Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 21:17-34 BIBELI MIMỌ (BM)

17. “Ìgbà mélòó ni à ń pa fìtílà ẹni ibi?Ìgbà mélòó ni iṣẹ́ ibi wọn ń dà lé wọn lórí?Tabi tí Ọlọrun ṣe ìpín wọn ní ìrora ninu ibinu rẹ̀?

18. Ìgbà mélòó ni wọ́n dàbí àgékù koríko,tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri,tabi bí ìyàngbò tí ìjì ń gbé lọ?

19. “O ní, ‘Ọlọrun ń to àìdára wọn jọ de àwọn ọmọ wọn.’Jẹ́ kí ó dà á lé wọn lórí, kí wọ́n baà lè mọ ohun tí wọ́n ṣe.

20. Jẹ́ kí wọ́n fi ojú ara wọn rí ìparun ara wọn,kí wọ́n sì rí ibinu Olodumare.

21. Kí ni ó kàn wọ́n pẹlu ilé wọn mọ́, lẹ́yìn tí wọn bá ti kú,nígbà tí a bá ti ké ọjọ́ wọn kúrò lórí ilẹ̀.

22. Ṣé ẹnìkan lè kọ́ Ọlọrun ní ìmọ̀,nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni onídàájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní ibi gíga?

23. Ẹnìkan kú ninu ọpọlọpọ ọrọ̀,nítorí pé ó wà ninu ìdẹ̀ra ati àìfòyà,

24. ara rẹ̀ ń dán fún sísanra,ara sì tù ú dé mùdùnmúdùn.

25. Ẹlòmíràn kú pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn,láìtọ́ ohun rere kankan wò rí.

26. Bákan náà ni gbogbo wọn ṣe sùn ninu erùpẹ̀,tí ìdin sì bò wọ́n.

27. “Wò ó! Mo mọ èrò ọkàn yín,mo sì mọ ète tí ẹ ní sí mi láti ṣe mí níbi.

28. Nítorí ẹ wí pé, ‘Níbo ni ilé àwọn eniyan ńlá wà;níbo sì ni àgọ́ àwọn aṣebi wà?’

29. Ṣé ẹ kò tíì bèèrè ọ̀nà lọ́wọ́ àwọn arìnrìnàjò?Ṣé ẹ kò sì tíì gba ẹ̀rí wọn, pé,

30. a dá ẹni ibi sí ní ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀,ati pé a gbà á là ní ọjọ́ ibinu?

31. Kò sẹ́ni tó jẹ́ fẹ̀sùn kan ẹni ibi lójú rẹ̀,tabi kí ó gbẹ̀san nǹkan burúkú tí ó ṣe.

32. Nígbà tí a bá gbé e lọ sí itẹ́,àwọn olùṣọ́ a máa ṣọ́ ibojì rẹ̀.

33. Ẹgbẹẹgbẹrun èrò a tẹ̀lé e lọ sí ibojì,àìmọye eniyan a sì sin òkú rẹ̀;kódà, ilẹ̀ á dẹ̀ fún un ní ibojì rẹ̀.

34. Nítorí náà, kí ni ìsọkúsọ tí ẹ lè fi tù mí ninu?Kò sóhun tó kù ninu ọ̀rọ̀ yín,tó ju irọ́ lọ.”

Ka pipe ipin Jobu 21