11. Wọn a máa kó àwọn ọmọ wọn jáde bí agbo ẹran,àwọn ọmọ wọn a sì máa ṣe àríyá.
12. Wọn a máa fi aro, ìlù, ati fèrè kọrin,wọn a sì máa yọ̀ sí ohùn dùùrù.
13. Wọn a máa gbé inú ọlá,wọn a sì máa kú ikú alaafia.
14. Wọ́n ń sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀!A kò fẹ́ mọ òfin rẹ.
15. Ta ni Olodumare, tí a óo fi máa sìn ín?Èrè wo ni ó wà níbẹ̀ fún wa bí à ń gbadura sí i?’
16. Wọ́n rò pé ìkáwọ́ wọn ni ọlà wọn wà,nítèmi n kò lè tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.
17. “Ìgbà mélòó ni à ń pa fìtílà ẹni ibi?Ìgbà mélòó ni iṣẹ́ ibi wọn ń dà lé wọn lórí?Tabi tí Ọlọrun ṣe ìpín wọn ní ìrora ninu ibinu rẹ̀?
18. Ìgbà mélòó ni wọ́n dàbí àgékù koríko,tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri,tabi bí ìyàngbò tí ìjì ń gbé lọ?
19. “O ní, ‘Ọlọrun ń to àìdára wọn jọ de àwọn ọmọ wọn.’Jẹ́ kí ó dà á lé wọn lórí, kí wọ́n baà lè mọ ohun tí wọ́n ṣe.
20. Jẹ́ kí wọ́n fi ojú ara wọn rí ìparun ara wọn,kí wọ́n sì rí ibinu Olodumare.