Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 21:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jobu dáhùn pé,

2. “Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáradára,kí ẹ sì jẹ́ kí ó jẹ́ ìtùnú fun yín.

3. Ẹ farabalẹ̀, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,lẹ́yìn náà, ẹ lè máa fi mí ṣẹ̀sín ǹṣó.

4. Ṣé eniyan ni mò ń bá rojọ́ ni?Kí ló dé tí n óo fi mú sùúrù?

5. Ẹ wò mí, kí ẹnu yà yín,kí ẹ sì fọwọ́ bo ẹnu.

6. Nígbà tí mo ro ohun tí ó dé bá mi,ẹ̀rù bà mí, mo sì wárìrì.

7. Kí ló dé tí eniyan burúkú fi wà láàyè,tí ó di arúgbó, tí ó sì di alágbára?

8. Àwọn ọmọ wọn ati arọmọdọmọ wọndi eniyan pataki pataki lójú ayé wọn.

9. Kò sí ìfòyà ninu ilé wọn,bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò jẹ wọ́n níyà.

10. Àwọn mààlúù wọn ń gùn,wọ́n sì ń bímọ ní àbíyè.

11. Wọn a máa kó àwọn ọmọ wọn jáde bí agbo ẹran,àwọn ọmọ wọn a sì máa ṣe àríyá.

Ka pipe ipin Jobu 21