Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 19:3-15 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ẹ kẹ́gàn mi ní àìníye ìgbàojú kò tilẹ̀ tì yín láti ṣẹ̀ mí?

4. Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé lótìítọ́ ni mo ṣẹ̀,ṣebí ara mi ni àṣìṣe mi wà?

5. Bí ẹ bá rò pé ẹ sàn jù mí lọ,tí ẹ sì rò pé ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi ni ìdààmú mi,

6. ẹ mọ̀ dájú pé Ọlọrun ni ó dá mi lẹ́bi,tí ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.

7. Mò ń kérora pé wọ́n dá mi lóró,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn;mo pariwo, pariwo,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dìde láti ṣe ẹ̀tọ́.

8. Ọlọrun ti dí ọ̀nà mọ́ mi, kí n má baà kọjá,ó mú ọ̀nà mi ṣókùnkùn.

9. Ó bọ́ ògo mi kúrò,ó sì gba adé orí mi.

10. Ó ba ayé mi jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà,ó sì ti parí fún mi,ó fa ìrètí mi tu bí ẹni fa igi tu.

11. Ibinu rẹ̀ ń jó mi bí iná,ó kà mí kún ọ̀tá rẹ̀.

12. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó ara wọn jọ,wọ́n dó tì mí,wọ́n sì pa àgọ́ tiwọn yí àgọ́ mi ká.

13. “Ó mú kí àwọn arakunrin mi jìnnà sí mi,àwọn ojúlùmọ̀ mi sì di àjèjì sí mi.

14. Àwọn ìyekan mi ati àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti já mi kulẹ̀.

15. Àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ sí ilé mi ti gbàgbé mi.Àwọn iranṣẹbinrin mi kà mí kún àlejò,wọ́n ń wò mí bí àjèjì.

Ka pipe ipin Jobu 19