Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 19:21-29 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ẹ ṣàánú mi, ẹ ṣàánú mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi,nítorí ọwọ́ Ọlọrun ti bà mí!

22. Ọlọrun ń lépa mi,ẹ̀yin náà sì tún ń lépa mi!Kí ló dé tí ẹran ara mi kò to yín?

23. “À bá lè kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀!Àní, kí á kọ ọ́ sinu ìwé!

24. Kí á fi kálàmú irin ati òjékọ ọ́ sórí àpáta, kí ó wà níbẹ̀ títí lae.

25. Ṣugbọn mo mọ̀ pé Olùdáǹdè mi ń bẹ láàyè,ati pé, níkẹyìn, yóo dìde dúró lórí ilẹ̀ yóo sì jẹ́rìí mi,

26. lẹ́yìn tí awọ ara mi bá ti díbàjẹ́,ṣugbọn ninu ara mi ni n óo rí Ọlọ́run.

27. Fúnra mi ni n óo rí i,ojú ara mi ni n óo sì fi rí i,kì í ṣe ti ẹlòmíràn.“Ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì ninu mi!

28. Bí ẹ bá wí pé, ‘Báwo ni a óo ṣe lépa rẹ̀!’Nítorí pé òun ló jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí,

29. ṣugbọn, ẹ bẹ̀rù idà,nítorí pé ìrúnú níí fa kí á fi idà pa eniyan,kí ẹ lè mọ̀ dájú pé ìdájọ́ ń bẹ.”

Ka pipe ipin Jobu 19