Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 19:14-21 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Àwọn ìyekan mi ati àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti já mi kulẹ̀.

15. Àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ sí ilé mi ti gbàgbé mi.Àwọn iranṣẹbinrin mi kà mí kún àlejò,wọ́n ń wò mí bí àjèjì.

16. Mo pe iranṣẹ mi, ṣugbọn kò dáhùn,bíbẹ̀ ni mo níláti máa bẹ̀ ẹ́.

17. Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ iyawo mi,mo sì ń rùn sí àwọn ọmọ ìyá mi.

18. Àwọn ọmọde pàápàá ń fojú tẹmbẹlu mi;bí mo bá dìde wọn á máa sọ̀rọ̀ sí mi.

19. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti rí mi sá,àwọn tí mo nífẹ̀ẹ́ ti kẹ̀yìn sí mi.

20. Mo rù kan egungun,agbára káká ni mo fi sá àsálà.

21. Ẹ ṣàánú mi, ẹ ṣàánú mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi,nítorí ọwọ́ Ọlọrun ti bà mí!

Ka pipe ipin Jobu 19