Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 18:8-21 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ó ti ẹsẹ̀ ara rẹ̀ bọ àwọ̀n,ó ń rìn lórí ọ̀fìn.

9. Tàkúté ti mú un ní gìgísẹ̀,ó ti kó sinu pańpẹ́.

10. A dẹ okùn sílẹ̀ fún un,a sì dẹ pańpẹ́ sí ojú ọ̀nà rẹ̀.

11. “Ìbẹ̀rù yí i ká,wọ́n ń lé e kiri.

12. Ebi pa agbára mọ́ ọn ninu,ìṣòro sì ti ṣetán láti gbé e ṣubú.

13. Àìsàn burúkú jẹ awọ ara rẹ̀,àkọ́bí ikú jẹ ẹ́ tọwọ́ tẹsẹ̀.

14. A fipá wọ́ ọ kúrò ninu àgọ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé,a sì mú un lọ sọ́dọ̀ Ọba Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀.

15. Àgọ́ rẹ̀ kún fún àwọn tí kì í ṣe tirẹ̀,imí-ọjọ́ fọ́nká sí gbogbo ibùgbé rẹ̀.

16. Gbòǹgbò rẹ̀ gbẹ nísàlẹ̀,ẹ̀ka rẹ̀ sì gbẹ lókè.

17. Ó di ẹni ìgbàgbé lórílẹ̀ ayé,bẹ́ẹ̀ ni a kò gbórúkọ rẹ̀ mọ́ ní ìgboro.

18. Wọ́n tì í láti inú ìmọ́lẹ̀ sinu òkùnkùn,wọ́n lé e kúrò láyé.

19. Kò lọ́mọ, kò lọ́mọ ọmọ,kò sì sí ẹni tí yóo rọ́pò rẹ̀ ní ibùgbé rẹ̀,láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

20. Ẹnu yóo ya àwọn ará ìwọ̀ oòrùn,ìwárìrì yóo sì mú àwọn ará ìlà oòrùn,nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí i.

21. Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé ẹni ibi yóo rí,àní, ilé ẹni tí kò mọ Ọlọrun.”

Ka pipe ipin Jobu 18