Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 18:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Bilidadi ará Ṣuha bá tún dáhùn pé,

2. “Ìgbàwo ni o óo sinmi ẹjọ́ tí ò ń tò yìí?Ohun tí a tí ń bá ọ sọ ni kí o gbé yẹ̀wò,kí á lè sọ èyí tí a tún fẹ́ sọ.

3. Kí ló dé tí o fi kà wá sí ẹranko,tí a di òmùgọ̀ lójú rẹ?

4. Ìwọ tí o faraya nítorí inú ń bí ọ,ṣé kí á sá kúrò láyé nítorí rẹ ni,tabi kí á ṣí àwọn àpáta nípò pada?

5. “Nítòótọ́, a ti pa fìtílà ẹni ibi,ahọ́n iná rẹ̀ kò sì mọ́lẹ̀ mọ́.

6. Inú àgọ́ rẹ̀ ṣókùnkùn,a sì ti pa àtùpà ìgbèrí rẹ̀.

7. Agbára rẹ̀ ti dín kù,ète rẹ̀ sì gbé e ṣubú.

8. Ó ti ẹsẹ̀ ara rẹ̀ bọ àwọ̀n,ó ń rìn lórí ọ̀fìn.

Ka pipe ipin Jobu 18