Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 17:8-16 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Èyí ya àwọn olódodo lẹ́nu,aláìlẹ́bi sì dojú kọ ẹni tí kò mọ Ọlọrun.

9. Sibẹsibẹ olódodo kò fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ sì ń lágbára sí i.

10. Ṣugbọn ní tiyín, bí ẹ tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ,n kò ní ka ẹnikẹ́ni kún ọlọ́gbọ́n láàrin yín.

11. “Ọjọ́ ayé mi ti dópin, èrò ọkàn mi ti dàrú,àwọn ohun tí ọkàn mi ń fẹ́ sì ti di asán.

12. Wọ́n sọ òru di ọ̀sán,wọ́n ń sọ pé, ‘Ìmọ́lẹ̀ kò jìnnà sí òkùnkùn.’

13. Bí mo bá ní ìrètí pé ibojì yóo jẹ́ ilé mi,tí mo tẹ́ ibùsùn mi sinu òkùnkùn,

14. bí mo bá pe isà òkú ní baba,tí mo sì pe ìdin ní ìyá tabi arabinrin mi,

15. níbo ni ìrètí mi wá wà?Ta ló lè rí ìrètí mi?

16. Ṣé yóo lọ sí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ni?Ṣé àwa mejeeji ni yóo jọ wọ inú erùpẹ̀ lọ?”

Ka pipe ipin Jobu 17