Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 17:3-12 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Fi nǹkan ẹ̀jẹ́ kan lélẹ̀ fún mi lọ́dọ̀ rẹ;ta ló wà níbẹ̀ tí yóo ṣe onídùúró fún mi?

4. Níwọ̀n ìgbà tí o ti mú ọkàn wọn yigbì sí ìmọ̀,nítorí náà, o kò ní jẹ́ kí wọ́n borí.

5. Bí ẹnìkan bá hùwà ọ̀dàlẹ̀, tí ó ṣòfófó àwọn ọ̀rẹ́,kí ó lè pín ninu ohun ìní wọn,àwọn ọmọ olúwarẹ̀ yóo jìyà.

6. O ti sọ mí di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn eniyan,mo di ẹni tí à ń tutọ́ sí lára.

7. Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,gbogbo ẹ̀yà ara mi dàbí òjìji.

8. Èyí ya àwọn olódodo lẹ́nu,aláìlẹ́bi sì dojú kọ ẹni tí kò mọ Ọlọrun.

9. Sibẹsibẹ olódodo kò fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ sì ń lágbára sí i.

10. Ṣugbọn ní tiyín, bí ẹ tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ,n kò ní ka ẹnikẹ́ni kún ọlọ́gbọ́n láàrin yín.

11. “Ọjọ́ ayé mi ti dópin, èrò ọkàn mi ti dàrú,àwọn ohun tí ọkàn mi ń fẹ́ sì ti di asán.

12. Wọ́n sọ òru di ọ̀sán,wọ́n ń sọ pé, ‘Ìmọ́lẹ̀ kò jìnnà sí òkùnkùn.’

Ka pipe ipin Jobu 17