Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 17:11-15 BIBELI MIMỌ (BM)

11. “Ọjọ́ ayé mi ti dópin, èrò ọkàn mi ti dàrú,àwọn ohun tí ọkàn mi ń fẹ́ sì ti di asán.

12. Wọ́n sọ òru di ọ̀sán,wọ́n ń sọ pé, ‘Ìmọ́lẹ̀ kò jìnnà sí òkùnkùn.’

13. Bí mo bá ní ìrètí pé ibojì yóo jẹ́ ilé mi,tí mo tẹ́ ibùsùn mi sinu òkùnkùn,

14. bí mo bá pe isà òkú ní baba,tí mo sì pe ìdin ní ìyá tabi arabinrin mi,

15. níbo ni ìrètí mi wá wà?Ta ló lè rí ìrètí mi?

Ka pipe ipin Jobu 17